Bàtà Ìwọ̀seré Aláwọ̀ Èsúrú
by Iquo DianaAbasi
First published as “Yellow Slipper” in Saraba Magazine (August 2014)
Translated into Yorùbá by Rasaq Malik
Narrated in Yorùbá by Rasaq Malik.
Rò ó wò.
Kí o sẹ̀sẹ̀ ṣe tán níbi iṣẹ́ lẹ́yìn ìgbaṣẹ́-fúnra tí ó pẹ́ – alẹ́ òhun àárọ̀ yí wọnú ara wọn nítorípé ilé ìwòsàn náà kò ní òṣìṣẹ́ tí ó pọ̀. Lẹ́yìn náà, o ṣe ìrọ́jú nípa ìrìn-àjò rẹ tí ó gùn ju b'óseyẹ lọ ní ojú ọ̀nà réèluwè tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ ní títì mároṣẹ̀ Bàdágàrí. Nígbà tí o rìn wọ inú ọgbà ilé kọjúsími-kín-kọjúsíọ rẹ, àgbá ìgbómi-pamọ́ ti GeePee tó wà lókè fún ẹbí méjì-dín-lọ́gbọ̀n ní inú ilé alájà kan náà àti àwọn yàrá bọ́ìsì tí ó lẹ̀ mọ ti kún dẹ́nu dé bi pé omi ń ṣàn yàlà káàkiri ẹ̀hìnkùlé wọ àwọn inú ilé tí ó sún mọ
Ò ń gbọ́ kíkùnyùn ohùn ẹ̀rọ kan, ṣùgbọ́n o rìn lọ sí ẹ̀gbẹ́ kejì ilé náà, ibí tí omi tí mù, o wá ṣàkíyèsí – lẹ́ẹ̀kan síi – pé pákó mẹ́ta tí ó gbé àgbá náà dúró tí ń yẹ̀gẹ̀rẹ̀ lábẹ́ ẹrù omi náà. O pa ẹ̀rọ-ìfami náà kí o tó rìn wọ inú ilé oníyàrá méjì rẹ tí ó wà ní ẹ̀yìn ilé náà.
Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú àwọn ọjọ́, o kò ní láti tò lórí ìlà kí o tó lo bawùlẹ̀, àti pe omi ẹ̀rọ ń yọ. O mọ́kàn láti yín irin amómiìwẹ̀-yọ tí ó ti dógùnún wò, omi sì ń jáde ní ibi ti o sún mọ́ díẹ̀ sí orí rẹ. Fún ìdí èyí, o sún mọ́ dèèdé abẹ̀ ẹnu ọ̀ṣọ̀rọ̀ náà, o sì ń jẹ̀'gbádùn bí omi náà ṣe jẹ́ kí ara rẹ balẹ̀ láti orí rẹ tí ó wà ní dídé pẹ̀lú fìlà-ìwẹ̀ títí dé èjìká tó ń ro ọ́, ẹ̀yìn àti ẹsẹ̀ rẹ. O mí síta.
Ní dèèdèé ìgbà tó ǹ da bíi ọgbọ́n láti sùn láti jẹ kí orí fífọ́ rẹ balẹ̀, o bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣàṣàrò ohun tí o fẹ́ pèsè fún Oriade, ọba ìlú kéréje tí ẹ jọ pín. Oúnjẹ alẹ́ a máa ń jẹ́ àpèjẹ kékeré, ó tún wá peléke lóni torí pé o kúrò nílé kí àkókò oúnjẹ alẹ́ ó tó tó lánàá. O bẹ̀rẹ̀ sí ní yẹ àwọn àpótí ìkóǹkan sí rẹ ati ẹrọ amúǹkan-tutù kékeré wò láti ri dájú pé èròjà tó péye wà fún ohun tí o fẹ́ ṣè. O ń yàwòrán bí Oriade ṣé ń jẹ àsáró náà pẹ́lù ẹ̀kún síbí ẹlẹ́muga sínú ọkàn rẹ.
Ìró ẹsẹ̀ tín-ín-rín – pẹlu àwọn ọ̀pọ̀lọlọ̀ ìdùnnú tí ma ń mú wá - le má ì tí ì j’ólúborí nínú ilé yín, sùgbọ́n o ní àrídájú láti jẹ́ kí àrò ìfẹ yín máa jò pẹ̀lú iná ìfẹ́ àṣẹ̀ṣẹ̀bẹ̀rẹ̀.
*
O pa sítóòfù tí ó súnmọ́ ẹnu ọ̀nà yàrá rẹ nígbà tí oúnjẹ náà kù fẹ̀rẹ̀ tí ó jiná, o gbé ìkòkò tí ó kún fún ẹ̀rún isu nínú omi ata tó ki tí o pèlò pẹ̀lú ẹja gbígbẹ àti edé, lọ sí inú yàrá rẹ.
Lákọ́kọ́, o gé úgú; lẹ́yìn náà, ní òdì kejì abọ́ pẹrẹṣẹ náà, o gé ata Nsukka tí ó máa ń jẹ kí ẹnu Oriade dami láìsídiwọ́. Ìrántí yìí ń rìn ọ́ níkàké.
O kó ẹ̀fọ́ náà pa mọ́ sínú ẹ̀rọ amúǹkan-tutù, o pinnu láti fọ́n-ọn sórí àsáró náà, láti gbé kaná díẹ̀ kí o tó bù fún un, kí o ba lè bùṣẹ́kù ní adùn àti ní àwọ̀. Ọ̀nà láti lọ sí ọkàn ọkùnrin ni inú rẹ̀. O sì ní ìrètí pé ọ̀nà tí ó lọ sí ìdílé tí ó ní àlàáfíà, tí ó sì lè so èso rere sì tún ni inú yìí kan náà.
Àgbá náà tún bẹ̀rẹ̀ láti ma da omi nígbà tí o ṣetán láti fẹ̀yìn lélẹ̀ fún ìṣẹ́jú díẹ̀, ò ń rò ó lọ́kàn pé tani ẹni tí ó tún sí àgbá omi náà padà láàrin wákàtí kan. Ó ṣe ẹ́ bíi kí o dágunlá sí, kí ẹlòmíràn náà le wá yanjú ẹ̀. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́ta, tí o kò lè gbe kúrò lórí ẹ̀mí rẹ pé síṣomi lófò kò dára, o ti ara rẹ lọ́pọnọ̀npọ́n kúrò lórí ibùsùn rẹ, o setán láti lọ ṣe ìkọlù fún omi tí ó ń ya dànù.
Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fun ọ láti bá ẹ̀rọ náà ní pípa ṣùgbọ́n tí ó sì ń fami gòkè.
Jìnnìjìnnì tí ó dà bò ọ́ látàrí ìdún kẹ̀kẹ̀ pákó lákọ̀ọ́kọ́, ìró ẹlẹ́ẹ̀kejì, àti ìdákẹ́jẹ́jẹ́ ti alẹ́ oṣù Agẹmọ tó tutù tí ó ń lékún síi bí irun ẹ̀yìn ọrùn rẹ ṣe nàró gbandi ní ìwarí fún òjò. Ní tẹ̀ńlétèlé, ǹkànkan ń tari ẹsẹ̀ rẹ àti ara lọ sí iwájú ilé náà.
Àkókò a máa dúró. Eléyìí ni wà á rò tí ó bá yá.
Báwo ni o tún ṣe le ṣàlàyé ìdákẹ́jẹ́ tí ó lágbára ní àsìkò tí o mú ọkàn dúró nígbà tí o rí àgbá GeePee tí ó há sí àárín pákó tí o tí là àti ìdún kẹ̀kẹ̀ ìgbẹ̀yìn bí pákó tí ó wà ní ìdábùú ti wọ́ sí òkè, ti àgbá náà sì ń gbọ̀n tewu-tewu, lẹ́ṣẹ̀ kan náà.
O gbọ́ bí o ṣe kébòsí bí o tí ń sáré alápàńtètè lọ sọ́dọ̀ ọ̀dọ́mọdé náà, pẹ̀lú pọ́ngilá aládùn ní ẹnu rẹ̀ àti bébì ìṣeré alakisa ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó jóko ní ilẹ̀, tí ó wọ sókótó kékeré ti Dora The Explorer.
'Ìbíyemí!'
*
Igbe ẹkún ọmọ náà tí ó ń han gan-an-ran jẹ́ n tó ń fi etí rẹ lọ́kàn balẹ̀; o kò sì fẹ́ fọwọ́ rẹ gbé òkú ọmọ mìíràn ní kíákíá báyìí lẹ́yìn èyí tó ṣẹlẹ̀ ní ER lálẹ́ àná. Ò ń rẹ ọmọ náà lẹ́kún ní ìwọ̀n bí agbára rẹ ṣe mọ nínú ibúdò kékeré tí àgbá tó fọ́ náà dá sílẹ́, bí o ṣé ń fọwọ́ pa èjìká òsì rẹ̀ níbi tí àmì ìbímọ jóko wọ́ọ́rọ́wọ́.
Ó gbá àkíyèsí rẹ mú fún ìgbà díẹ̀. Ní ìrántí tí kò já geere, o ṣàkíyèsí ẹ̀jẹ̀ bíntín ní apá rẹ tí o fi ṣèṣe. Ẹsẹ̀ òsì Ìbíyemí náà kò móríbọ́; o rí èyí pẹ̀lú bí ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣé ń mì dirọdirọ, ṣùgbọ́n o mú dára rẹ lójú pé àtúnṣe sì wá fún ní déédéé ọjọ́ orí rẹ̀.
Nígbà tí ìyá rẹ̀ sáré bọ́ síta látí inú kọ̀rọ̀ tí ó wà láààrin ilé níbi tí yàrá rẹ̀ wà - irun tó dàrú, ìró pupa tí kò fẹ́ ẹ̀ bo ọyàn rẹ̀, àti ẹyọ bata iwosere alawo esuru ti Ilé-ìwẹ̀ kan ṣoṣo ní ẹsẹ̀ rẹ̀ – ò ń retí kó pariwo l'óhùn tantan, kò sì já ọ kulẹ̀ ní tòótọ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrora ńlá.
'Ọlọ́run óò! Ọmọ mi!! Ẹ gbà mí o! Mo dáràn o!
Àwọn ìṣesí àti ohun ìyàlẹ́nu ńlá, tí ó ṣeéṣe kí ó mu jà ara rẹ̀ sí ihoho nínú àgbàlá tí ó kún fún omi, ṣe kòńgẹ́ ìrètí rẹ.
Sùgbọ́n o kò nírètí à ti rí i.
O jáde wá sí ọwọ́ àlàáfíà rẹ̀ látẹ̀yìn; ojú rẹ̀ tí ń yọ̀ láàrin ìyàlẹ́nu àti ẹ̀rù, àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó wọ̀ lódìlódì, ẹsẹ̀ rẹ̀ wà nínú bàtà ìwọ̀seré ẹsẹ̀ òsì méjì; ìkan nínú wọn jọ ti arábìnrin náà pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn aláwọ̀ ewé tí o rà fún ní oṣù méjì sẹ́yìn.
Oríadé rẹ!
Rò ó wò!